Orin Ọ̀ṣun
Àní omi ò l’ápá omi gbégi
Omi ò l’ẹ́sẹ̀ omi gbénìyàn lọ o
Ìforó ayé mi omi gbé lọ
Ìforó ayé mi omi gbé lọ
Ìganá ayé mi omi gbé lọ
Ìforó ayé mi omi gbé lọ
Gbogbo abíkú ayé mi omi gbé lọ
Oore yèyé Ọ̀ṣun oo oore yèyé ìyá o
Oore yèyé Ọ̀ṣun oo oore yèyé ìyá o
Oore yèyé Ọ̀ṣun ìyá mi oore yèyé ìyá o