Iṣẹ́ l’oògùn ìṣẹ́ |
Adwuma yɛ ohia aduro |
Iṣẹ́ l’oògùn ìṣ̣ẹ́, múra síṣẹ́ ọ̀rẹ́ mi, iṣẹ́ ni a fi ń dẹni gíga. |
Adwuma yɛ ohia ano aduro, hyɛ wo sapɔ mu nsuo yɛ adwuma m’adamfo, adwuma na yɛde yɛ nnipa akɛseɛ. |
Bí a kò bá rẹ́ni fẹ̀yìn tì, bí ọ̀lẹ là ń rí. |
Sɛ yɛnni obi a yɛtumi dan no a, yɛte sɛ akwadwofoɔ. |
Bí a kò bá rẹ́ni gbẹ́kẹ̀lé; a tẹra mọ́ iṣẹ́ ẹni. |
Sɛ yɛnni obi a ɔbɛgyina yɛn akyi a, ɛwɔ sɛ yɛyɛ yɛn ankasa yɛn adwuma. |
Ìyá rẹ lè l’ówó l’ọ́wọ́; ki bàbá rẹ sì l’ẹ́ṣin l’éèkàn |
Wo na tumi nya sika bebree, w’agya tumi nya apɔnkɔ bebree. |
Bí o bá gbójú lé wọn, o tẹ́ tán ni mo ń sọ fún ọ. |
Wotwɛn wo na ne w’agya, sɛ wobɛyɛ adeɛ ma wo a, w’anim agu aseɛ awie na mereka akyerɛ wo. |
Ṣe bí ohun tí a kò bá jìyà fún; kìí lè tọ́jọ́ |
Sɛɛ na adeɛ a yɛmmrɛ ansa na yɛanya no; ntumi nkyɛ. |
Ohun tí a bá fara ṣiṣẹ́ fún; l’ó ń pẹ́ l’ọ́wọ́ ẹni. |
Nneɛma a yɛde yɛn ho na ɛyɛ adwuma ma saa adeɛ no; ɛno na ɛkyɛ wɔ obi nsa mu. |
Apá l’ará, ìgunpá niyèkan. |
Basa yɛ yɔnko, batwɛ yɛ onua. |
Bí Ayé bá ń fẹ́ ọ l’ónìí, bí o bá l’ówó l’ọ́wọ́ ni wọ́n máa fẹ́ ọ l’ọ́la. |
Sɛ wiase pɛ wo nnɛ a, wowɔ sika na wɔbɛpɛ wo ɔkyena. |
Tàbi kí o wà nípò àtàtà, Ayé á yé ọ sí tẹ̀rín tẹ̀rín. |
Anaa sɛ wowɔ dibea papa, wiase de seresere na ɛbɛkamfo wo. |
Jẹ́ kí o dẹni tí ń ráágó, kí o rí i bí Ayé ti ń yínmú sí ọ. |
Sɛ wo dane obi a ɔdi hia, hwɛ sɛdeɛ wiase tweaa wo. |
Ẹ̀kọ́ sì tún ń sọni í dọ̀gá, múra kí o kọ́ ọ dáradára. |
Adesua dane na ɛdane obi nipa kɛseɛ, yere wo ho sua no yie. |
Bí o sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń fẹ̀kọ́ ṣẹ̀rín rín; ṣọ́ra kí o má fara wé wọn. |
Bí o sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń fẹ̀kọ́ ṣẹ̀rín rín; ṣọ́ra kí o má fara wé wọn. |
Torí ìyà ń bọ̀ fọ́mọ tí kò gbọ́n; ẹkún ń bẹ fọ́mọ tí ń sá kiri. |
Ɔbrɛ reba ɛde ama akwadaa a ɔnnim nyansa; anisuo wɔ hɔ de ma akwadaa a ɔtu mmirika basabasa. |
Má fòwúrọ̀ ṣeré ọ̀rẹ́ mi; múra síṣẹ ọjọ́ ń lọ. |
Mfa anɔpa nni agorɔ m’adamfo, yere wo ho sua adeɛ berɛ na ɛrekɔ. |