Ìjàpa kógun jà ilé Odídẹrẹ́

Ní aiyé àtijọ́, Ìjàpa àti Odídẹrẹ́ jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ fùn Ògòngo tí í ṣe Ọba àwọn ẹiyẹ gbogbo. Ní ọjọ́ kan, Ọba fẹ́ dán Ìjàpá wò bóyá yio rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.

 Ọba sọ pé, ‘Ẹni tí iṣu rẹ̀ bá dán tí ó sì tóbi jù ni ng ó ṣe olórí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mi; ẹni tí iṣu rẹ̀ kò bá dára tó, ng ó nà á ni ẹgba méjìlá ní ìdí rẹ̀ ng ó sì lé e jáde ní ààfin mi.’

 Àwọn méjééjì dì iṣu wọn, nwọ́n múra, nwọ́n ḿbọ̀ ní ilé. Nígbàtí Ìjàpa délé, ó fi iṣu jiṣẹ́ fún Ọba gẹ́gẹ́ bi iṣu tirẹ̀, ó sì ròhin fún un pé eré ni Odídẹrẹ́ ńṣe lóko.

Inú bi Ọba rékọja pé Odídẹrẹ́ t’óun ti f’ọkàn tán l’ó  wá fì’dí òun jálẹ̀ bệ. Ó bá mú kòbókò rẹ̀ sítòsí ó pè àwọn géńdé, ẹiyẹ méjìlá, àwọn Àṣá, Àtíòro, Àgbìgbò, Igún, Ọ̀sìn àti bệ bệ lọ, nwón wà nítòsí.

Ògòngò re, alágbára ni, ẹgba kọ̀ọ̀kan t’ó ńfún Odídẹrẹ́ nídi, ìdí rẹ̀ ḿb’ẹ́jè ni, gbogbo ṣòkòtò rẹ̀ l’ó di pupa fòò fún ẹ̀jẹ̀ tí ńṣẹ́yọ nídi rẹ̀ nígbàtí Ògòǹgò ńnà á.

Àlọ́ yi kọ́ wa pé kì ṣọ́ra lọ́dọ̀ ọ̀rẹ́, kí a kíyèsí ìwa ẹnìkẹ́ni dáadáa kí a tó gbé ara lé e gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ o.