Àkókò ń lọ

Àkókò ń lọ, àkókò ń bọ̀,
Àkókò kò dúró d’ẹnìkan,
Ṣiṣẹ́ púpọ̀; ṣeré díẹ̀,
Nítorí pé àkókò rẹ l’ó ń lọ.

Àkókò ń lọ, àkókò ń bọ̀,
Àkókò kò dúró d’ẹnìkan,
Ṣeré púpọ̀; k’o sá f’íbi,
Nítorí pé àkókò rẹ l’ó ń lọ.

Àkókò ń lọ, àkókò ń bọ̀,
Àkókò kò dúró d’ẹnìkan,
Sa ‘pá púpọ̀; k’o sá f’ẹ́wọ̀n,
Nítorí pé àkókò rẹ l’ó ń lọ